Ìlò Àkànlò èdè nínú Àwọn Ìwé Ìtàn Àròsọ Ọladẹ̀jọ Òkédìjí

Oladejo Okediji's use of Language in his novels


Bachelor Thesis, 2017

82 Pages, Grade: 83.2%


Excerpt


ORÍ KÌÍNÍ ÌPÌLẸ̀ṢẸ̀ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ

1.0 Ìfáàra

Èdè jẹ́ ọ̀nà kan tí à ń gbà bá ara wa sọ̀rọ̀. Ọpẹ́yẹmí (2015:21) ṣàlàyé pé èdè ni ariwo tí ó ti ẹnu àwa ènìyàn jáde tí ó ní ìtumọ̀, tí ó ní iṣẹ́ láti jẹ́ fún ẹni tí ó gbọ́ ọ, tí ó ní ìlànà kan pàtó tí àwọn elédè ń tẹ̀lé, tí ó sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún gbogbo àwọn olùsọ èdè náà. Èdè ni òpómúléró fún iṣẹ́ lítíréṣọ̀, láì sí èdè, kò lè sí àtiwáyé iṣẹ́ lítíréṣọ̀. Oríṣiríṣi ọ̀nà ni àwọn elédè ń gbà mú èdè wọn rẹwà yálà ní sísọ lẹ́nu tàbí nínú kíkọ sílẹ̀. Gbogbo àwọn èdè tó gbajú-gbajà ní àgbáyé bí Èdè Gẹ̀ẹ́sì, Faransé, Potogí, Lárúbáwá, Swàhílì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ló ní àwọn ọnà amédè-rẹwà fún afọ̀. Èyí kò sì yọ èdè Yorùbá sílẹ̀. Àwọn ìpèdè bẹ́ẹ̀ ni àwọn onímọ̀ pè ní àwọn “Ọnà-èdè", wọ́n sì máa ń mú kí afọ̀ Yorùbá kún fún ìmọ̀, ìtumọ̀ àti òye. Irúfẹ́ àwọn ìpèdè bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí èdè ṣákálá tàbí àsọ̀jẹ ọ̀rọ̀ lásán. Àwọn ìpèdè yìí dúró gẹ́gẹ́ bí òpó fún afọ̀. Àwọn òpó wọ̀nyí ni àwọn Gẹ̀ẹ́sì pè ní “Figures of Speech”. Èyí fihàn pé gbogbo èdè ló ní tirẹ̀. Orúkọ tí èdè kọ̀ọ̀kan ń pe tirẹ̀ ló yàtọ̀. Ọnà-èdè ni àwọn hóró ọ̀rọ̀ tàbí àwọn ìpèdè tí aṣafọ̀ múlò láti mú adùn wọ afọ̀ rẹ̀, oríṣiríṣi sì ni àwọn ọnà-èdè tí a ní nínú èdè Yorùbá, lára wọn ni òwe, àkanlò-èdè, àwítúnwí, àsọrégèé, ìfọ̀rọ̀dárà, ìfìrósínròjẹ, Ìbádọ́gba gbólóhùn, àfiwé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ìlò àkanlò-èdè nínú iṣẹ́-ọnà Yorùbá ló jẹ iṣẹ́ yìí lógún. A lo tíọ́rì ìfojú ìhun-tí-ó-so-pọ̀-mọ́-ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ mọ́ lítíréṣọ̀ tú àwọn àkànlò-èdè Yorùbá gẹ́gẹ́ bí ó ṣe hàn nínú ìwé ìtàn àròsọ Àjà ló lẹrù àti Àgbàlagbà Akàn tí a gbé yẹ̀wò nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí. Iṣẹ́ yìí ṣe àfihàn ìlò àkànlò-èdè, ìṣẹ̀dá rẹ̀, ìhun àti ìwúlò àkànlò-èdè nínú ìwé ìtàn àròsọ wọ̀nyí láti fi pàtàkì ìlò èdè yìí hàn nínú iṣẹ́ aláwòmọ́ lítíréṣọ̀.

Orí kííní yìí dálé ṣíṣe àlàyé lórí kókó ohun tí iṣẹ́ yìí ìwádìí yìí dálé, a ṣàlàyé ohun tí ó gún wa ní kẹ́ṣẹ́ láti dágbá lé iṣẹ́ ìwádìí yìí, lẹ́yìn náà ni a ṣe àgbékalẹ̀ ìwúlò tí ó jẹyọ lára ṣíṣe iṣẹ́ ìwádìí yìí. A ṣe àfihàn èròngbà tí iṣẹ́ yìí ní. Ọgbọ́n ìwádìí tí a múlò ni ó tẹ̀lé èyí níbi tí a ti ṣe àfihàn onírúurú ọnà ti a gbà láti ṣe àkójọ èròjà tí a múlò fún ìwádìí yìí. Ibi tí iṣẹ́ ìwádìí yóò gbòòrò dé náà jẹyọ níbi tí a ti ṣàlàyé ibi tí iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ àti ibi tí yóò dé. Ètò Ìwádìí náà kò gbẹ́yìn nígbà tí àfihàn ìtàn ìgbésí ayé òńkọ̀wé ní ó kádìí orí náà.

1.1 Èrèdí Ìwádìí

Oríṣìíríṣìí ìwádìí ló ti wáyé lórí ọnà èdè pàápàá ìlò rẹ̀ nínú iṣẹ́ lítíréṣọ̀ ṣùgbọ́n àkíyèsí wa ni pé àwọn aṣèwádìí ò kọbi ara sí ìlò àkànlò èdè nínú iṣẹ́ ọnà alátinúdá. Iṣẹ́ ìwádìí ò fi bẹ́ẹ̀ sí lórí ìlò àkànlò èdè nínú iṣẹ́ lítíréṣọ̀, tí a bá wo àwọn iṣẹ́ lámèyítọ́ tó ń jáde lórí lítíréṣọ̀ Yorùbá, àwọn aṣewádìí ò mú ìlò èdè gẹ́gẹ́ bíi òkúnkúndùn. Àjàyí (2003) tí ó sọ̀rọ̀ lórí ìlò èdè Òkédìjí kan ṣe àlàyé díẹ̀ lórí bí Òkédìjí ṣe lo àwọn ọnà èdè nínú iṣẹ́ rẹ̀ pàápàá òwe, èyí sì jẹ́ ọ̀kan lára ohun tí ó gún wa ní kẹ́sẹ́ inú láti dágbá lé abala èdè yìí gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìwádìí wa.

Pàtàkì àkànlò èdè jẹ́ ohun tí àwọn onímọ̀ èdè ti fúnka mọ́ pé ó yẹ kí ìwádìí tẹ̀síwájú lórí rẹ̀. Moreno (2011) tọ́ka sí ìdí mẹ́ta tí ó fi yẹ kí a ka àkànlò èdè sí ohun tí ó ṣe pàtàkì, àkọ́kọ́ nipé lílo àkànlò èdè daadaa máa ń jẹ́ kí ènìyàn gbọ́ tàbí mọ èdè daada, àti pé lílo ọnà èdè jé atọ́ka sí pé ènìyàn gbọ́ èdè náà dé ojú àmì, ó tún tẹ̀síwájú pé àkànlò èdè màa ń fún ènìyàn ní iwúrí nípa àṣà, ìṣe àti èdè.

Lójúmọ́ tó mọ́ lonìí, àìmọye iṣẹ́ ìwádìí ló ti wáyé lórí àwon ìtàn àròsọ Ọládẹ̀jọ Òkédìjí pẹ̀lú tíọ́rì kan tàbí òmìíràn. Àjàyí àti Olábọ̀dé (2003) ṣe àgbéyẹ̀wò mẹ́ta nínú àwọn ìwé ìtàn àròsọ Òkédìjí (Àjà ló l'ẹru, Àgbàlagbà Akàn ati Atótó Arére), Akínyẹmí (1993) ṣiṣé lórí "Ìlò Ìnagijẹ bí Ìfìwàwẹ̀dá nínú àwọn Ìwé ìtàn àròsọ Òkédìjí ''. Ó wo bí Òkédìjí ṣe lo ìnagijẹ láti ṣe àpèjúwe àwọn ẹ̀dá ìtàn rẹ̀. Bámidúró (1984) ṣiṣẹ́ lórí "Ọládẹ̀jọ and the Trickster Tradition' ', Bámidúró wo ìwà jàndùkú àti ìwà ọ́daràn bí ó ṣe jẹyọ nínú àwọn iṣẹ́ Òkédìjí, Barber (1982) ṣiṣẹ́ lórí Style and Ideology in Fágúnwà and Òkédìjí, ohun tó jẹ́ Barber lógún nínú iṣẹ́ rẹ̀ ni wíwo ọgbọ́n ìṣọwólo-èdè àti kókó tàbí èròngbà tó wà nínú iṣẹ́ Fágúnwà àti Òkédìjí, Momodu (1982) ṣe àlàyé pé ìyànjú láti dẹ́kun ìwá ìbàjẹ́ tó ń ràn lẹ́yìn ìgbà tí epo rọ̀bì dé àwùjọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ló jẹ́ kókó èròngbà àwọn òǹkọ̀wé ìwé ìtàn àròsọ nínú Ìtàn Àròsọ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Yorùbá, Ògúnṣínà (1988) nínú The Sociology of the Yorùbá Novels: A study of Isaac Délànà, D. O. Fágúnwà and Óládẹjọ ṣe àtúpalẹ̀ ìwà àwùjọ, Sheba (2005) náà lo iṣẹ́ rè Ọládẹ̀jọ Òkédìjí Ingenious use of Proverbs: Evidence from his Crime Novels láti fi pín oríṣi òwe tí Òkédìjí múlò.

Bí iṣẹ́ ṣe pọ̀ tó lórí àwọn ìwé ìtàn àròsọ Òkédìjí, kò sí iṣẹ́ àtúpalẹ̀ kankan lórí ìlò àkànlò èdè tàbí ọ̀nà ìṣọwọ́lo àkànlò èdè nínú iṣẹ́ rẹ̀. Ìyànjú láti dí àlàfo yìí tún jẹ́ ọ̀kan lára kókó ohun tí a fi yan abala yìí láàyò fún iṣẹ́ ìwádìí wa.

1.2 Èròngbà Ìwádìí

Èròngbà ìwádìí yìí ni láti ṣe àfìhàn ète tí Òkédìjí dá láti fi àkànlò èdè fa kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ. A ṣe àtúpalẹ̀ ìhun àti ààtò àwọn àkànlò èdè tí a rí ṣà jọ nínú Àjà ló lẹrù àti Àgbàlagbà Akàn.

Èròngbà ìwádìí yìí ni láti tọ pinpin àbùdá àdámọ́ àkànlò-èdè mọ̀ yàtọ̀ sí àwọn ọnà èdè yóókù. Síwájú si, iṣẹ́ yìí ṣe ìgbéléwọ̀n àti àfiwé ìlò àmì nínú àkànlò èdè g̣ẹ́gẹ́ bí Òkédìjí ṣe lò ó nínú ìwé méjèèjì.

1.3 Ìwúlò Iṣẹ́ Ìwádìí

Iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò fi kún ìmọ̀ wa lórí ẹ̀kọ́ nípa ìṣọwọ́lo èdè Óládẹjọ Òkédìjí pàápàá jùlọ ọ̀nà tí ó ń gbà lo àkànlò èdè, yóò fi kún ìmọ̀ wa bákan náà lórí ìyàtọ̀ láàrin ìtumọ̀ tí a fún ọ̀rọ̀ tàbí ìpèdè kan lérèféé àti ìtumọ̀ ìjìnlẹ̀ tí irúfé ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ní.

Àfikún ni iṣẹ́ yìí yóò jẹ́ lórí àkànlò èdè torí iṣẹ́ yìí yóò ṣe àwárí, àgbéyẹ̀wò àti ìtumọ̀ àwọn àkànlò èdè tí òńkọ̀wé múlò nínú iṣẹ́ rẹ̀. Bákan náà ni iṣẹ́ yìí á tún jẹ́ àfikún fún ohunkóhun tí ó ti wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀ lórí ìlò èdè nínú àwọn ìwé ìtàn àròsọ Òkédìjí.

Èyí nìkan kọ́, iṣẹ́ yìí yóò tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìlò àkànlò èdè jẹ́ irinṣẹ́ kan pàtàkì lọ́wọ́ oníṣẹ́ ọnà àti pé àkànlò èdè ní àtò àti ìhun tirẹ̀. Ní ìkáàdí, Tíọ́rì ìfojú ìhun-tí-ó-so-pọ̀-mọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ tí a múlò yóò ṣe àfihàn àkànlò èdè gẹ́gẹ́ bí àmì àrokò kan láti fi bánisọ̀rọ̀.

1.3 Ọgbọ́n Ìwádìí

Nínú Iṣẹ́ ìwádìí yìí, a lọ sí agbègbè Apààrà ní ìlú Ọ̀yọ́ láti lọ ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú òńkọ̀wé tí a gbé iṣẹ́ rẹ̀ yẹ̀wò lórí ìtàn ìgbésí ayé òǹkọ̀wé àti lórí iṣẹ́ àtinúdá wọ́n ti ṣe.

Òmìíràn ni lílọ sí yàrá ìkàwé láti ka àwọn iṣẹ́ àpilẹ̀kọ ajẹmọ́kadá àti àpilẹ̀kọ iṣẹ́ ìwádìí tí àwọn aṣáájú ti ṣe lórí àkànlò èdè àti àwọn ìwé Òkédìjí bóyá lédè Gẹ̀ẹ́sì tàbí ní èdè Yorùbá fúnra rẹ̀.

A tún ṣe àmúlò àkọsílẹ̀ lórí ẹ̀rọ íńtánẹ́èṭì torí pé ní ayé òde òní a ṣe àkíyèsí pé kò sí abala tàbí ẹ̀ka ìmọ̀ kan tí kò ní àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀ lórí ẹ̀rọ ìtàkùn àgbáyé. Ọgbọ́n ìṣàtúpalẹ̀ alálàyé ni a lò fún ìtúpalẹ̀ àwọn àkànlò èdè tí a kó jọ.

1.5 Ibi Tí Ìwádìí Yóò Gbòòrò Dé

Ohun tí ó jẹ iṣẹ́ ìwádìí lógún ni àgbéyẹ̀wò àwọn àkànlò èdè nínú ìwé ìtàn àròsọ Àjà ló l'ẹrù àti Àgbàlagbà Akàn tí Ọládẹ̀jọ Òkédìjí kọ. Iṣẹ́ yìí wo irú àkànlò èdè tí ó jẹyọ nínú àwọn ìwé ìtàn àròsọ náà. Aáyan ọ̀mọ̀ràn wa fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé onírúurú àkànlò èdè ló wà, a ní àkànlò èdè aṣẹ̀dá, àkànlò èdè tuntun, àkànlò àyálò, àkànlò èdè onígbólóhùn, ẹlẹ́yọ ọ̀rọ̀ àti aláwẹ̣́ gbólóhùn, a tún wo bí òńkọ̀wé ṣe lò wọ́n àti bi àwọn Yorùbá ṣe ń lò wọ́n.

Tíọ́rì tí a ó gbé iṣẹ́ wa ka ni tíọ́rì ìmọ̀ nípa ìfojú ìhun-so-pọ̀-mọ́ àwùjọ (Genetic Structuralism) pọ̀ mọ́ tíọ́rì ajẹmáwùjọ (Sociology).Ní ìkádìí a ó ṣe àtóòlẹ̀ àwọn àkànlò èdè tó súyọ nínú àwọn ìwé ìtàn àròsọ náà pẹ̀lú ìtumọ̀ wọn.

Orí kííní dé ìkarùn-ún ni iṣẹ́ ìwádìí yìí. Ìfáàrà ló ṣíde ní orí kọ̀ọ̀kan. Orí kííní ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí wa. Lẹ́yìn ìfáàrà, a ṣe àfihàn ohun tó bí iṣẹ́ yìí nípa sísọ èrèdí iṣẹ́ ìwádìí náà. Lẹ́yìn èyí lo kan èròngbà iṣẹ́ ìwádìí, ibi tí ìwádìí gbòòrò dé, ọgbọ́n ìwádìí tí a lò, ìwúlò tí iṣẹ́ ìwádìí yìí ní, ètò ìwádìí àti ìtàn ìgbésí ayé òńkọ̀wé tí a lò ló kádìí orí yìí nílẹ̀.

Orí kejì ni Aáyan ọ̀mọ̀ràn wa. Gẹ́gẹ́ bí i ti orí kííní, ìfáàrà ló ṣáájú, àwọn kókó tí a yẹ̀wò ní orí kejì ni èrò àwọn onímọ̀ nípa èdè, lítíréṣọ̀, ìbáṣepọ̀ láàrin lítíréṣọ̀ àti àwùjọ, láàrin lítíréṣọ̀ àti èdè, àkànlò èdè gẹ́gẹ́ bí ọnà èdè nínú lítíréṣọ̀ àti iṣẹ́ àwọn ará iwájú lórí ìtàn àròsọ Òkédìjí, àyẹ̀wò ohun tí tíọ́rì tí a múlò dálé ló kádìí orí náà.

Orí kẹta ni ìtúpalẹ̀ ìhun àti kókó ọ̀rọ̀ àwọn ìwé tí a túpalẹ̀. Ifáàrà ló bẹ̀rẹ̀ orí kẹta bákan náà, a ṣe àwárí àwọn ohun tó jẹ́ àtègùn fún iṣẹ́ Òkédìjí, kókó inú ìtàn àròsọ méjèèjì, àwọn ẹ̀dá ìtàn àti ọgbọ́n tí Òkédìjí lò láti sẹ̀dá ìtàn rẹ̀, a ṣe àgbéyẹ̀wò ọgbọ́n ìsọ̀tàn tí ó lò. Ìlò èdè nínú àwọn ìtàn àròsọ náà ni a fi ṣe àṣekágbá orí náà.

Orí kẹrin náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìfáàrà, a ṣe àtúpalẹ̀ àwọn àkànlò èdè tí òńkọ̀wé lò nínú ìwé méjèèjì yìí pẹ̀lú tíọ́rì ìfojú ìhun-tí-o-so-pọ̀-mọ́-ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ. A ṣe àfihàn ìtumọ̀ wọn lérèféé àti ìtumọ̀ ìjìnlẹ̀ tí wọ́n ní àti ọ̀nà tí òńkọ̀wé gbà lò wọ́n. Ní orí karùn-ún tó jẹ́ ìkẹyìn ni ìsọníṣókí àbọ̀ ìwádìí yìí wà, ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú tẹ̀le, ìgúnlẹ̀ iṣẹ́ ló sì gbẹ̀yìn orí yìí.

1.5 Ìtàn Ìgbésí Ayé Óládẹjọ Òkédìjí

A bí Ọládẹ̀jọ Òkédìjí ní ìlú Ọ̀yọ́ ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹwàá ọdún 1929 sí ìdílé onígbàgbọ́, òun ló ṣìkejì ọmọ mẹ́ta tí àwọn òbí rẹ̀ bí. Àgbẹ̀ paraku ni bàbá rẹ̀ Moses Òkédìjí títí tí ó fi kú ní ọjọ́ kejìlélógún oṣù Èbìbì ọdún 1976, onígbàgbọ́ òdodo sì ni pẹ̀lú ìyá Ọládẹ̀jọ Òkédìjí Marian Oyeèwùmí tí ó ṣì wà láyé di àkókò yìí.

Ìlú Ọ̀yọ́ ni Ọládẹ̀jọ Òkédìjí ti ṣe kékeré rẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni ó sì máa ń lọ sí Igbó Ajé láti lọ ran bàbá rẹ̀ lọ́wọ́ ní oko. Ó bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé nígbà tí ó di ọmọ ọdún mẹ́ta. Ó lọ sí ilé-ìwé Elétò ti Ápáàrá, Ọ̀yọ́ láàrin ọdún 1935 sí 1941. Ó lò ọdún méjì yòókù (1945-1948) láti fi parí ìwé mẹ́fà rẹ̀ ní ilé-ìwé Áńdérù Mímọ́ ní ìlú Ọ̀yọ́ kan náà. Lẹ́yìn ìwé mẹ́fà, Òkédìjí lọṣe iṣẹ́ olùkọ́ni ní Fìdítì létí Ọ̀yọ́ kí ó tó lọ lo ọdún mẹ́rin ní Wesley College (1945-1948) láti kọ́ iṣẹ́ olùkọ́ni onípò kejì. Lẹ́yìn tí ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ló bẹ̀rẹ̀ sí sisẹ́ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ olùkọ́ni ní àwọn ìlú bíi Ìjẹ̀bú-òde, Ọ̀wọ̀, Èkó, Àkúrẹ́ àti Ilé-Ifẹ̀.

Ní sáà ètò ọdún 1975/76, Yunifásítì Ilé-Ifẹ̀ gba Óládẹjọ Òkédìjí láti kọ́ ẹ̀kọ́ ọdún kan fún ìwé èrí olùkọ́ onípò-kìn-ín-ni. Láti ọdún 1976 tó ti parí ẹ̀kọ́ náà ni ó ti ń kọ́ àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ gíga Ọ̀rànmíyàn Grammar School, Ilé-Ifẹ̀ ní èdè Yorùbá.

Ọládẹ̀jọ Òkédìjí ṣe ìgbeyàwó ní ọdún 1953, ọmọ Ìdó-Ànì létí Ọ̀wọ̀ ni Ìyàwó rẹ̀, Christiánà Ọmọlará, ọmọ márùn-ún, obìnrin mẹ́rin àti ọkùnrin kan ni wọ́n bí; gbogbo àwọn ọmọ náà ni wọ́n ti gòkè àgbà báyìí.

Láti ọdún 1954 ni Òkédìjí ti ní ìṣírí nípa ìwé kíkọ, nígbà tí Ìgbìmọ̀ Alábẹṣékélé fún Lítíréṣọ̀ Yorùbá ní Ìpínlẹ̀ Iwọ̀ Oòrùn àtijọ́ ṣe ìkéde pé àwọn ń fẹ́ ọmọ Yorùbá tó lè kọ ìtàn àròsọ tí kò ní àwọn abàmì ẹ̀dá bíi ti inú ìwé Fágúnwà. Fún ìdí èyí, Òkédìjí kọ̀wé bèèrè lọ́wọ́ ìgbìmọ̀ náà bóyá wọn lè gba ìtàn àròsọ kan Àgbàlagbà Akàn tí òun tó kọ tẹ́lẹ̀. Òkédìjí kò gbọ́ èsì kankan títí ó fi di ọdún 1960, tí ó gbọ́ pé Ilẹ́-Iṣẹ́ Ètò Èkọ́ Ìpínlẹ̀ Ìwọ̀ Oòrùn ń wá òun kiri. Kí ó tó lọ yọjú sí wọn, àkókò ti ń lọ fún ìdíje kíkọ ìtàn àròsọ fún ayẹyẹ gbígba òmìnira ní ọjọ́ kín-ín-ní oṣù Ọ̀wàrà ọdún 1960.Kí a máa fa ọ̀rọ̀ gùn, wọ́n ṣe ìdíje náà, Fẹ́mi Jẹ́bodà ló fi ìwé rẹ̀ Olówólayémọ̀ gba ipò kì-ín-ní.

Nígbà tí ó di 1966, Ọ̀mọ̀wé Babalọlá tó ti di Ọ̀jọ̀gbọ́n báyìí kọ sínú ìwé ìròyìn kan wí pé òun fẹ́ mọ ibi tí arákùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Óládẹjọ Òkédìjí wà. Kò pé kò jìnnà, Òkédìjí yọjú sí Babalọlá. Òkédìjí bèèrè èrò Babalọlá nípa ìtàn àròsọ tí ó fi ṣọwọ́ sí Ọ̀jọ̀gbọ́n náà ṣùgbọ́n Babalọlá kò rí ìtàn àròsọ tí Òkédìjí fi ṣowọ́ sí i fún ìtọ́sọ́nà mọ́. Nǹkan tó burú jù ni pé Òkédìjí kò ní ẹ̀da ìtàn náà lọ́wọ́, ó sì ṣòro fun láti rántí gbogbo ohun tó kọsílẹ̀ lẹ́sẹsẹ, iyán di àtúgún, ọ̀bẹ di àtúnsè ni Òkédìjí fi kọ ìwé rẹ̀ àkọ́kọ́ Àjà ló lẹrù ní 1969.

Nígbà tí ó di 1971, ó tún kọ ìwé mìíràn tó pè ní Àgbàlagbà Akàn, ṣùgbọ́n ìtàn inú rẹ̀ kò lè ṣàì yàtọ̀ sí èyí tó sọnù ní ìjọ́sí. Láti ìgbà náà ló ti ń kọ ìwé oríṣiríṣi. Ó ti kọ ìtàn àròsọ fún ọmọdé àti àgbà, eré oníṣe àti ìwé ìbéèrè àti ìdáhùn fún àwọn tó ń ṣe ìdánwò Yorùbá sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga. Àwọn ìwé tí Òkédìjí ti kọ ni a tò sí ìsàlẹ̀ yìí;

1. Àjà ló lẹ́rù, 1969.
2. Àgbàlagbà Akàn, 1971.
3. Ọ̀gá ni Bùkọ́lá, 1972.
4. Rẹ́rẹ́ Rún, 1973
5. Ìmúra Ìdánwò Yorùbá, 1978.
6. Atótó Arére, 1981.
7. Ṣàngó, 1985.
8. Bínú ti rí, 1986.
9. Ọ̀pá Àgbéléká, 1987.
10. Aájò Ajé, 1997.
11. Running after Riches, 2001.
12. Ká Rìn Ká Pọ̀, 2007.

Àjà ló lẹrù àti Àgbàlagbà Akàn ni a gbé yẹ̀wò nínú iṣẹ́ yìí .

ORÍ KEJÌ AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN

2.0 ÌFÁÀRÀ

Orí kejì yìí ṣe àgbéyẹ̀wò èrò àwọn onímọ̀ nípa èdè àti lítíréṣọ̀, ìbáṣepọ̀ tó wà láàrin lítíréṣọ̀ àti èdè, ìbáṣepọ̀ tó wà láàrin lítíréṣọ̀ àti àwùjọ, pàtàkì tí ọna-èdè ní nínú iṣẹ́ lít́réṣọ. Lẹ́yìn náà ni a ṣe yìí ṣe àfihàn ohun tí àwọn onímọ̀ kan ti sọ lórí àkànlò èdè, àwọn iṣẹ́ ọ̀kan-ọ̀- jọ̀kan tó ti wáyé lórí àwọn ìwé Òkédìjí ló tẹ̀le nígbà tí àlàyé lórí tíọ́rì tí a múlò kádìí orí yìí.

2.1 ÈRÒ ÀWỌN ONÍMỌ̀ NÍPA ÈDE

Oríṣiríṣi àwọn onímọ̀ ló ti ṣe àpèjúwe ohun tí èdè jẹ́. Èdè jẹ́ àtòpọ̀ ìró tí ó di ọ̀rọ̀ àti ọ̀rọ̀ tí a tò pọ̀ di gbólóhùn. Gbólóhùn sì ni à ń lò láti gbé èrò ọkàn wa jade. Ní èrò Henry Sweet (1945:8):

Language is the expression of ideas by means of speech sounds combined into words. Words are combined into sentences, this combination resulting to ideas and thoughts. Èdè jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì tí a fi ń gbé èrò ọkàn wa jáde nípasẹ̀ ìró tó parapọ̀ di ọ̀rọ̀, aàtòpọ̀ ọ̀rọ̀ ló di gbólóhùn Èyí túmọ̀ pé èdè jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì tí a fi ń sọ èrò ọkàn wa di ọ̀rọ̀ fún aráyé gbọ́. Bákan náà Tinúoyè (1994) ní “Language is an instrument of thought or concept,It gives a vivid expression to human thoughts. Èyí túmọ̀ pé èdè jẹ́ irinṣẹ́ tí a fi ń gbé ìrònú tàbí èrò jáde,o máa ń sàlàyé ohun tí èdá ń rò lọ́kàn. Oríkì tí Pearson àti àwọn yóókù (2003:74) ki èdè fihàn pé:

Language is a collection of symbols, letters or words with arbitrary meaning that are governed by rules and used to communicate.

Èdè jẹ́ àkójọpọ àwọn àmì, lẹ́tà, ọ̀rọ̀ yìí kò dá ìtumọ̀ ní, ohun tí a gbà pé wọ́n ń jẹ́ náà ni wọ́n ń jẹ́. Ìlànà àjọsọ tẹ̀lé òfin tí a fẹnu kò lé lórí ní àwùjọ láti fún wọn ní ìtumọ̀.

Tí a bá wo èrò àwọn onímọ̀ òkè wọ̀nyí dáadáa, a ó rí i pé èrò wọn fẹnu kò pé èdè ni ọ̀nà kan tí à ń lò láti ṣe àgbékalẹ̀ èrò inú wa yálà nípa ṣíṣe àfọ tàbí ṣíṣe àkọsílẹ̀.

Táíwò (2016:29) ṣàlàyé pé èdè ṣe pàtàkì, omọ ènìyàn ní ń sọ èdè, èdè ló mú ẹ̀dá ènìyàn yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀dá mìíràn tí Olódùmarè dá sílé ayé. Èyí ni pé èdè jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ìhùwàsí ènìyàn.Ó sì ní ìbáṣepọ̀ tó yii pẹ̀lú ìgbé ayé ọmọ ènìyàn. Èdè ní ó jẹ́ kí ìbágbépọ̀ ẹ̀dá rọrùn. Èdè ni a fi ń tan ìmọ̀, òun sì ni atọ́nà fún àṣà.

Oríṣiríṣi ọnà ni à ń gbà lo èdè, onírúurú iṣẹ́ ni a sì ń lò èdè fún. Hockett (1963:16) gbìyànjú láti sọ̀rọ̀ lórí ohun tí a lè pè ní iṣẹ́ èdè. Ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ bíi Bloomfield (1914:3), Crystal (1947:239), Barber (1964:9) ló ṣàpèjúwe ohun tí à ń fi èdè ṣe, wọ́n fi yé wa pé èdè ni a fi ń ronú, èdè ni a fi ń gbé èrò ọkàn ẹni síta, òun ni a fi ń kọ́ni, a ń fi kẹ́kọ̀ọ́, à ń lò ó láti fi búni, láti fi ṣe àpọ́nlé ẹni, láti fi tàbùkù ẹni, láti fi kíni, láti fi yọ̀, láti fi kẹ́dùn, láti fi ṣòwò-nájà, láti fi polongo .

Eno Lowenfeld (1970) nínú iṣẹ́ Chumbow (1985:1) sọ onírúurú ohun tí a lè fi èdè ṣe, Ní èrò rẹ̀:

Language can be used to sooth, anger, excite, tranquilize, stimulate, intimidate, energize, stultify, create, destroy, assassinate or immortalize.

A lè fi èdè tú ènìyàn nínú, múni bínú, tunilára, fi ènìyàn lọ́kàn balẹ̀, márayá, dẹ́rùbani,mú dúró, ṣẹ̀dá, ba nǹkan jẹ́, tàbí láti sọ nǹkandi mánigbàgbé .

Láì sí àní-àní èdè lágbára, ó sì wúlò púpọ̀ , àwọn onímọ̀ ò fọwọ́ rọ́ ipa tí èdè ń kó láwùjọ ọmọ ènìyàn sẹ́yìn, wọn fi yé wa pé èdè jẹ́ òpómúléró nínú ìṣesí ẹ̀dá láyé, kò sì ṣeéṣe láì lo èdè fún ohunkóhun tí ẹ̀dá bá fẹ́ ṣe láyé.

2.2 ÌBÁṢEPỌ̀ LÁÀRIN ÈDÈ ÀTI ÀṢÀ

Oríṣiríṣi onímọ̀ ló ti sọ̀rọ̀ lórí ìbáṣepọ̀ tó wà láàrin èdè àti àṣà àwùjọ. Ní èrò Goodenough (1957) nínú iṣẹ́ Wardhaugh (2002:219);

Culture is whatever it is one has to know or believe in other

to operate in a manner acceptable to it’s members.

Àṣà ni ohunkóhun tí ènìyàn gbọ́dọ̀ mọ̀ láti lè fi hùwà ní ọ̀nà tí ó jẹ́

ìtẹ́wọ́gbà ní àwùjọ tí ènìyàn wà.

Freimuth (2006:1) rí àṣà gẹ́gẹ́ bí:

The accumulated habits, attitudes, and beliefs of a group

of people that define for them their general behaviour and

way of life.

Àkójọpọ̀ àwọn ìwà, ìṣe, ojú tí wọ́n fi ń wo ayé àti ìgbàgbọ́

àwọn ènìyàn tí ó máa ń ṣe atọ́nà fún ìhùwàsí wọn àti irú

ìgbésí ayé tí wọ́n ń gbé.

Èrò àwọn onímọ̀ wọ̀nyí fi hàn pé àṣà jẹ́ àkójọpọ̀ ìmọ̀ nípa ìgbésí ayé àwọn ẹ̀yà tàbí àwùjọ kan, ìgbàgbọ́, ìṣe àti ìhùwàsí wọn àti pé àṣà ló ń darí èrò báyéṣerí àwùjọ. Àmì ìdánimọ̀ ni àṣà jẹ́. Bí wọ́n ṣe ń wọ aṣọ, jẹun, ṣe iṣẹ́ àti sọ ọ̀rọ̀ pàápàá jẹ́ àmì ìdánimọ̀ fún wọn. Hymes (1964:29) ṣe àfihàn èdè gẹ́ge bí kò-ṣe-má nìí inú àṣà tí àwọn ènịyàn fi ń bá ara wọn sọ̀rọ̀:

Speech is so fundamental an activity of man, language so

intergral a part of his culture

Afọ̀ ṣíṣe ṣe pàtàkì láàrin ọmọ ènìyàn, èdè sì jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àṣà rẹ̀

Hymes fi yé wa pé èdè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ inú àṣà, èdè ni ó máa ń fi irú àṣà tí ènìyàn tí wá hàn. Witherspoon (1980:2) ní tirẹ̀ wòye pé a ò lè kọ́ nípa èdè láì ní ìmọ̀ nípa àṣà tàbí àwùjọ tó ti ṣẹ̀ wá. Èyí ni pé ara àṣà àwùjọ ni èdè wọn wà. Èdè ni a fi ń kọ́ nípa àṣà. Gẹ́gẹ́ bí èrò Wardaugh (2002:219) èdè ló ń gbé àṣà àwọn ènìyàn síta:

The culture of a people finds reflection in the language they

employ because they value certain things and do them in a

certain way, they come to use their language in ways that reflect

what they value and what they do.

Àfihàn àṣà àwọn ènìyàn kan máa ń wáyé nínú èdè tí wọ́n ń sọ

nítorí pé wọ́n káràmásìkí àwọn ohun kan tí wọ́n sì ní ònà tí wọn

ń gbà ṣe é; wọn a ma mú èdè lò láti ṣe àfihàn irúfẹ́ ohun tí wọ́n

káràmásìkí àti ohun tí ó jẹ́ ìṣe wọn

Àyọlò yìí fihàn pé èdè àti àṣà wọnú ara wọn. Èdè ló ń ṣe àfihàn àṣà àwùjọ. A ò lè ṣe aláì má rí ìjẹyọ àṣà nínú èdè. Èdè ni a fi ń ṣe ìgbélárugẹ fún àṣà, àwùjọ tí èdè rẹ̀ bá sì parẹ́ ti sọ àṣà rẹ̀ nù nítorí èdè ni a fi ń tan àṣà láti ìran dé ìran. Èdè ń gbé àṣà yọ, òun ló ń ta àṣà fún ayé, àṣà náà lè di títán kálẹ̀ nípasẹ̀ èdè. Èyí lè rọrùn tí a bá fi èdè kọ lítíréṣọ̀, irú èyí tí Òkédìjí ṣe nínú Àjà ló lẹrù àti Àgbàlagbà Àkàn.

2.3 ÈRÒ ÀWỌN Ọ̀MỌ̀RÀN NÍPA LÍTÍRÉṢỌ

Oríṣiríṣi ni oríkì ni àwọn onímọ̀ ti fún lítíréṣọ̀ káàkiri àgbáyé, oríṣìíríṣìí àpèjúwe rẹ̀ ní àwọn ọ̀mọ̀ràn sì ti ṣe pẹ̀lú. Ọ̀péfèyítìmí (1997:3) wòye pe lítíréṣọ̀ ni iṣẹ́ òńkọ̀wé alátinúdá tàbí iṣẹ́ tó níṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀, ìlò ojú inú gẹ́gẹ́ bí ewì, ìtàn àròsọ àti eré-oníṣe tí ó kó púpọ̀ nínú ìmọ̀ ìgbé ayé ẹ̀dá láwùjọ mọ́ra, yálà a kọ ọ́ sílẹ̀, a rò ó sọ tàbí a ṣe é léré .

Nínú oríkì tí Ọ̀pẹ́fèyítìmí fún wa yìí, ó fara mọ pé èdè tí a ṣe lọ́nà ni lítíréṣọ̀ jẹ́ àti pé lítíréṣọ̀ pín sí ọ̀nà méjì gbòógì, ìyẹn lítíréṣọ̀ alohùn àti lítíréṣọ̀ alákọsílẹ̀.Yorùbá. Onímọ̀ mìíràn Babalọlá nínú iṣẹ́ Ọpẹ́fèyítìmí (1997:4) wòye pé Iítíréṣọ̀ ni àkójọpọ̀ ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ ni èdè kan tàbí òmìíràn, ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ tó jásí ewì, àlọ́, ìtàn, ìròyìn, ìyànjú, eré-onítàn, eré akọ́nilọ́gbọ̀n lórí ìtàgé. Ó tún fi kun un pé kó sì tó di kíkọ sílẹ̀ tàbí àtẹ̀jáde, lítíréṣọ̀ lè wà ní ọpọlọ àwọn ọ̀mọ̀ràn.

Àwọn onímọ̀ méjèèjì òkè yìí ló gbà pé èdè tó yàtọ̀ sí èdè ojoojúmọ́ ni lítíréṣọ̀ jẹ́ àti pé òun náà pín lítíréṣọ̀ sí ọ̀nà méjì, àkọ́kọ́ ni lítíréṣọ̀ alohùn àti lítíréṣọ̀ alákọsílẹ̀. Jimoh (2016:147) náà pín lítíréṣọ̀ sí ìsọ̀rí méjì, àkọ́kọ́ ni lítíréṣọ̀ alohùntí ó jẹ mọ́ ìtàn, ewì àti eré-oníṣe ti ìbílẹ̀. Ìpín kejì ni lítíréṣọ̀ àpilẹ̀kọ níbi tí a ti rí ewì àpilẹ̀kọ, ìtàn àròsọ ọlọ́rọ̀ geere pẹ̀lú eré-oníṣe àpilẹ̀kọ tí a jogún lọ́wọ́ àwọn òyìnbó lẹ́yìn tí ìmọ̀ mọ̀-ọ́-kọ mọ̀-ọ́-kà dé tán.

Ògúnṣínà (1998:6) ṣàpèjúwe lítíréṣọ̀ gẹ́gẹ́ bí èdè tí a ṣe ní ọnà tí ó kún fún àkànlò èdè tó gbádùn àti èdè àgbọ́mirí. Onímọ̀ yìí gbà pé inú lítíréṣọ̀ alohùn ló wọ́pọ̀ sí.

Moody (1968) sọ pé ojúṣe lítíréṣọ̀ ni láti dánilárayá lọ́nà tó gba ọgbọ́n láàyè káàyé àti nígbà kúùgbà. Gẹ́gẹ́ bí Zugbaul (1986:12) ṣe sọ. Ó gbà pé a lè gbọ́ èdè nípa kíkọ lítị́réṣọ̀ èyí ló jẹ́ kí ó dábàá kíkọ́ lítíréṣọ̀ nínú ètò ẹ̀kọ́. Wàyí o, ẹ jẹ́ kí a ṣe àgbéyẹ̀wò ìbáṣepọ̀ tí ó lọ́rìn tó wà láàrin lítíréṣọ̀ àti èdè.

2.4 ÈRÒ ÀWỌ̀N ONÍMỌ̀ NÍPA ÌBÁṢEPỌ̀ TÓ WÀ LÁÀRIN LÍTÍRÉṢỌ̀ ÀTI ÈDÈ

Duhan (2015:195 ) wòye pé

A close look at literature and language shows that the

two are closely related. This close relationship is obvious

because from all indications, language presupposes literature.

It is inconceivable to discuss literature without reference to

language through some characters who, by their words,action and

reaction, convey certain messages for the purpose of

education,information and entertainment.

Tí a bá wo lítíréṣọ̀ àti èdè daadaa, a ó ri pé àwọn méjèèjì

wọnú ara wọn pẹ́kí pẹ́kí, ìbáṣepọ̀ pẹ́kí pẹ́kí yìí hàn gan

nítorí ní gbogbo ọ̀nà, kò lè sí lítíréṣọ̀ láì sí èdè, ó sì ṣòro láti

jíròrò lórí lítíréṣọ̀ láì mẹ́nubà èdè láti ọwọ́ àwọn ẹ̀dá kan tí ó

gbè àwọn èrò kan jáde fún ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́, ìlanilọ́yẹ̀ nípa ọ̀rọ̀, ìṣe

àti ìhùwàsí wọn àti ìdánilárayá.

Ohun tí onímọ̀ yìí ń gbìyànjú láti sọ ni pé ìbáṣepọ̀ tó dúró ṣinṣin ló wà láàrin lítíréṣọ̀ àti èdè, a ò lè mẹ́nuba lítíréṣọ̀ láì sọ nípa èdè, èyí farapẹ́ èrò Ihejirika (2014:4) tó sọ pé

Literature is rooted in language and language gets life

through literature.So Literature and language are closely

interconnected.

Lítíréṣọ̀ gbilẹ̀ sínú èdè, èdè sì máa ń ẹ̀mí nípasẹ̀ lítíréṣọ̀,

tori náà lítíréṣọ àti èdè wọnú ara wọ́n pẹ́kí pẹ́kí.

Ihejirika tún tẹ̀síwájú láti sọ pé

The basic element in Literature that is indispensable that can be deduced

from the definition under reference is the fact that Literature, no matter

the type or genre, is written in words. This is to say that language is the

basic raw material with which literature is manufactured. It is based on this

view that it is usually said that “Literature is language in practice”. That is

to say that language theories, concepts and styles are put into function in the

creation of literary texts. Literature and language are not only intertwined

but also inter-related.

Èròjà kan pàtàkì tí ó jẹ́ kòsẹ́máàní nínú lítíréṣọ̀ ni èdè, èyí jẹyọ lára ọ̀rọ̀ tó

sọ pé kò sí ìsọ̀rí iṣẹ́ lítíréṣọ̀ kankan tí a ò lo ọ̀rọ̀ láti ṣẹ̀dá rẹ̀, èyí nipé èdè ni

èròjà kan pàtàkì tí a fi ń ṣẹ̀dá iṣẹ́ lítíréṣọ̀, èyí ló wá fà á tí a máa fi ń sọ pé iṣẹ́

èdè tó ń lọ lọ́wọ́ ni lítíréṣọ̀ jẹ́. Èyí wá túmọ̀ pé èrò, tíọ́rì àti ìṣọwólo-èdè ni a

hun pọ̀ láti sẹ̀dá iṣẹ́ lítíréṣọ̀, Lítíréṣọ̀ àti èdè so mọ́ ara wọ́n, wọ́n tún ní ìbáṣepọ̀

pẹ́kí pẹ́kí pẹ̀lú ara wọ́n.

A wòye pé àwọn onímọ̀ òkè yìí fẹnu kò pé láti ara èdè ni a ti ṣe àwárí lítíréṣọ̀, èdè tí a ṣe ní ọ̀ṣọ́ ni lítíréṣọ̀ jẹ́, ìyapa kúrò nínú èdè ojoojúmọ́ ni o bí iṣẹ́ lítíréṣọ̀.

2.5 ÈRÒ ÀWỌN ONÍMỌ̀ NÍPA ÌBÁṢEPỌ̀ TÓ WÀ LÁÀRIN LÍTÍRÉṢO ÀTI ÀWÙJỌ

Lítíréṣọ̀ ò lè jẹ jáde láti inú àwùjọ kan láì ní ìrapa tàbí ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú irú àwùjọ bẹ́ẹ̀, èyí ló mú Duhan (2015:192) wòye pé

Literature indeed reflects the society, its good values and its ills. In

its corrective function, literature mirrors the ills of the society with

a view to making the society realize its mistakes and make amends.

It also projects the virtues or good values in the society for people to

emulate. Literature, as an imitation of human action, often presents a

picture of what people think, say and do in the society. In literature, we

find stories designed to portray human life.

Àwòjìji àwùjọ ni lítíréṣọ̀ jẹ́, ó máa ń ṣe àfihàn ohun tó da àti

èyí tí kò da nínú àwùjọ kan, lítíréṣọ̀ maá ń ṣe àfihàn ìwà ìbàjẹ́

àwùjọ kan pẹ̀lú ìlàkàkà láti jẹ́ kí àwùjọ rí àsìṣe rẹ̀, kí ó sì ṣe

àtúnṣe. Ó tún máa ń ṣe ìgbéjáde àwọn ìwà rere tí ó yẹ kí àwọn

ènìyàn inú àwùjọ máa wù. Lítíréṣọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìsínjẹ ìwà ènìyàn sábà

máa ń ya àwòrán àwọn ohun tí ènìyàn ń rò, sọ àti ṣe nínú àwùjọ.

Nínú lítíréṣọ̀, a máa ń ṣalábápàdé àwọn ìtàn tí a gbé kalẹ̀ lọ́nà tí

yóò ṣàfihàn ìgbé ayé ẹ̀dá.

Durbey (2013:2) wòye pé

Literature cannot sustain without society, and

likewise the society too cannot be unnoticed in literary

pieces in one way or another.

Lítíréṣọ̀ ò lè dúró láì sí àwùjọ, bákan náà a ò lè ṣe aláì

máa rí àfihàn àwùjọ nínú iṣẹ́ lítíréṣọ̀ lọ́nà kan tàbí òmííràn .

Tí a bá wá wo èrò àwọn onímọ̀ òkè yìí, a ó rí i pé ìbáṣepọ̀ tó wà láàrin àwùjọ àti lítíréṣọ̀ kìí ṣe èyí tó ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn, àwọn méjèèjì ń bá ara wọ́n ṣiṣẹ́ nı. Lítíréṣọ̀ máa ń ṣe àfihàn èrò báyéṣerí àwùjọ, òun ló ń ṣàfihàn ohun tó ń lọ láwùjọ, ó sì ní agbára láti ṣe àfọ̀mọ́ fún ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ. A ò lè ṣiṣẹ́ lórí lítíréṣọ̀ láì ṣe àgbéyẹ̀wò irú àwùjọ tí iṣẹ́ lítíréṣọ̀ bẹ́ẹ̀ ti jẹ jáde, èrò báyéṣeri àwùjọ ni lítíréṣọ̀ jẹ́. Àwọn ohun tó ń lọ nínú àwùjọ ni lítíréṣọ̀ máa ń ṣe àfihàn àti àgbéjáde. Lítíréṣọ̀ ló máa ń gbé èrò báyéṣerí àwùjọ jáde

2.6 PÀTÀKÌ ỌNÀ-ÈDÈ NÍNÚ IṢẸ́ LÍTÍRÉṢỌ

Àwọn ohun mẹ́ta tí ó gbé lítíréṣọ̀ ró ni Èdè, Akópa àti Ìṣẹ̀lẹ̀. Láì sí èdè, kò lè sí àwọn èròjà méjì yóókù torí pé èdè ni a máa lò láti ṣe àgbékalẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ àti ipa tí àwọn akópa kó. Bí ó ti wá wù kí èdè ṣe pàtàkì tó, pàtàkì rẹ̀ kó tó mímọ̀ lò . Oríṣìí ọ̀nà ni oníṣẹ́ ọnà lítíréṣọ̀ ń gbà láti fi ọ̀rọ̀ dárà. Ìyẹn ni à ń pè ní ọnà-èdè. Àwọn ọnà-èdè yìí jẹ́ ohun tí ó ń gbé èdè Yorùbá níyì. Kò sí ọ̀nà tí a lè gbà láì fara pẹ́ gírámà èdè Yorùbá nítorí pé èdè ló kọ́kọ́ wà kí a tó máa yọ àwọn ọ̀rọ̀ kan nínú rẹ̀ fún àpọ́nlé èdè náà.

Gẹ́gẹ́ bí èrò Awótáyọ̀ (1987:1); Ọnà-èdè ni àwọn ọ̀rọ̀ tí a ṣẹ̀dá láti mú adùn afọ̀ Ìmọ̀ yìí tẹ̀lé ìmọ̀ àwọn ọ̀mọ̀ràn. Èyí ni pé kí ènìyàn tó lè sọ̀rọ̀ ní àwùjọ, kí a sì kan sáárá si, ó gbọ́dọ̀ múlò nínú àwọn ọnà èdè Yorùbá yálà nípa sísọ tàbí nípa kíkọ sílẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ara èdè náà ni a ti ń fà àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyìí yọ, ẹwà tí wọ́n ń dá padà ju bí ọ̀rọ̀ ṣe wà tẹ́lẹ̀ lọ.

Èròjà pàtàkì ni ọnà-èdè jẹ́ fún lítíréṣọ̀, ipa tí wọ́n ń kó nínú iṣẹ́ kan kì í ṣe kèrémí. Bí ènìyàn bá ń sọ pé ìtàn àròsọ, eré-onítàn tàbí ewì kan dùn, kì í ṣe ìwé gan-an ni ó dùn bí kò ṣe àwọn ọnà-èdè tí ó sodo sínú ìwé náà.

Ọmọníyì (2002:57) ki ọnà-èdè gẹ́gẹ́ bíi àwọn hóró ọ̀rọ̀, àpólà tàbí gbólóhùn tí aṣafọ̀ lò láti mú adùn èdè wọnú afọ̀ rẹ̀. Ó tẹ̀síwájú pé ọnà-èdè dàbí irú nínú ọbẹ̀, ìmọ́ọ́lò wà fún un, bí irú kìí tí ba obẹ̀ jẹ́ náà ni ọ̀pọ̀ ọnà-èdè kì í ṣe aburú fún iṣẹ́ lítíréṣọ̀. Àmọ́ àṣìlò rẹ̀ lè pagidínà àgbọ́yé, ó sì le má jẹ́ kí ète àti èrò aṣafọ ó jọ. Bí aṣafọ̀ bá ṣi ọnà-èdè lò, ìdíwọ́ yóò wà fún ìfèrò ráńṣẹ́, nípa bẹ́ẹ̀, ohun tí ń sọ kò ní ní ìtumọ̀ sí olùgbọ́.

Ẹ̀wẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a máa ń lo ọnà-èdè nínú èdè ojoojúmọ́ síbẹ̀, ìlò rẹ̀ nínú iṣẹ́ lítíréṣọ̀ ju ti èdè ojoojúmọ́ lọ, torí pé iṣẹ́ lítíréṣọ̀ jẹ́ iṣẹ́ ọnà. Oríṣiríṣi ọnà-èdè ló wà. Lára wọn ni; òwe, àkanlò-èdè, àfiwé, ìfọ̀rọ̀dárà, ìfohunpènìyàn, gbólóhùn adọ́gba, ìfìrósínroojẹ, àdàpè, àsọrégèé, ọ̀rọ̀-bí-òwe. Òwe àti àkanlò-èdè gbajúmọ̀ nínú àwọn ọnà-èdè Yorùbá. Ipò àti ipa tí àkanlò-èdè àti òwe ń kó náà ni gbogbo àwọn ọnà-èdè yòókù ń kó. Èyí túmọ̀ sí pé àparò kan ò ga ju ìkan lọ.

2.7. ÀKÀNLÒ-ÈDÈ GẸ́GẸ́ BÍ Ọ̀KAN LÁRA ÈRÒJÀ LÍTÍRÉSỌ̀

Babátúndé (2005:22) sọ pé àwọn Yorùbá máa ń lo ojúlówó èdè láti fi ṣe àgbékalẹ̀ èrò wọn yálà nínú ọ̀rọ̀ sísọ tàbí nínú ìwé, ó jẹ́ ki ó yé wa pé lára ìpèdè bẹ́ẹ̀ ni òwe, àkànlò èdè, ìfọ̀rọ̀dárà, àsọrégèé, àyúnlọ-àyúnbọ̀ gbólóhùn, dídọ́gba gbólóhùn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. L'ábẹẹ ọnà èdè Yorùbá ló sì pín gbogbo àwọn ìpèdè wọ̀nyí sí.

Gbogbo èdè ní àgbáyé ló ní àwọn ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ àti ọnà amédèrẹwà, tí ìtumọ̀ wọn kò lè yé ẹni tí kò bá gbọ́ èdè náà dunjú. Irú ọnà èdè sọ ènìyàn di ọ̀gbẹ̀rì. Èdè Yorùbá náà ní àwọn ìpèdè wọ̀nyí, tí ó lè mu kí ó ṣòro fún ẹni tí kò mọ àṣà àti èdè ìlú náà láti mọ ìtumọ̀ ìjìnlẹ̀ àwọn ìpèdè bẹ́ẹ̀. Ọ̀kan lára irú ibi tí èdè Yorùbá gbé ta kókó, tí ó sì lè sọ ènìyàn di òpè ni nípa lílo àkanlò-èdè.

Àkanlò-èdè yìí jẹ́ ọ̀kan lára ọnà-èdè tí àwọn Yorùbá máa ń lò láti mú kí ohun tí wọ́n ń sọ lọ́ọ̀rìn, kí ó sì ní ìtumọ̀ ìjìnlẹ̀ tí wọ́n ń fẹ́. Ó fara pẹ́ òwe ṣùgbọ́n kìí ṣe òwe. Oyèbánjí (1990:98) ki àkanlò-èdè gẹ́gẹ́ bí:

Kánàkò ni a lè fi àkanlò-èdè wé. Ìdí ni pé bí gbólóhùn

àkanlò-èdè ṣe máa ń kúrú tó nì, ohun tí tọ́rọ́ bá ṣe

ẹgbẹ̀rún ìdọ̀bálẹ̀ kò lè ṣe é ló jẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbólóhùn

ṣókí ni a fi máa ń gbé àkanlò-èdè kalẹ̀, síbẹ̀ ìtumọ̀ rẹ̀ máa

jinlẹ̀ tí yóò sì rinlẹ̀ gbingbin.

Olúnládé (2003:13) náà ki àkanlò-èdè báyìí;

Àkanlò-èdè ni àwọn ọ̀rọ̀, àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tàbí àpólà tí

a gbọ́dọ̀ kó ní àpapọ̀. Ìdí tí a fi gbọ́dọ̀ kó wọn papọ̀ ni pé

kò ní fún wa ní ìtumọ̀ àkanlò-èdè bí a kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ ..

Àkanlò-èdè ni àwọn òǹkọ̀wé àtijọ́ máa ń tọ́ka gẹ́gẹ́ bí

àgbéká tàbí àdìtú èdè.

Abídoyè (2014:41) wòye pé lílo àkanlò-èdè tún máa ń jẹ́ kí a mọ bí ènìyàn ṣe gbọ èdè Yorùbá tó. Ẹni tí ó gbọ́ èdè Yorùbá dáadáa yóò lè lọ onírúurú àkanlò-èdè bí ó bá ń sọ̀rọ̀, yóò sì mọ ìtumọ̀ rẹ̀ bí wọ́n bá ba sọ.

Síwájú si, Babátúndé (2005:22) ki àkànlò èdè gẹ́gẹ́ bí àwọn ìpèdè kan tí a ti kan ìtumọ̀ rẹ̀ kan pàtó mọ àwọn ìtumọ̀ kan. Irú ìtumọ̀ tí a kàn mọ́ ìpèdè bẹ́ẹ̀ máa ń yàtọ̀ sí ìtumọ̀ tí a lè fún ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn lérèféé. Bí àpẹẹrẹ tí Yorùbá bá sọ pé “abẹ́ ge e”, ìtumọ̀ gbólóhùn yìí lérèféé nípa bí àwọn ọ̀rọ̀ inú gbólóhùn náà ṣe tò pọ̀ ni pé irú ọ̀bẹ kan tí a mọ̀ sí abẹ́ ti ge kiní kan. Ṣùgbọ́n èyí kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, ìtumọ̀ àkànlò èdè ọ̀hún ni pé "ó parí"” tàbí a ti pa á láṣẹ.

[...]

Excerpt out of 82 pages

Details

Title
Ìlò Àkànlò èdè nínú Àwọn Ìwé Ìtàn Àròsọ Ọladẹ̀jọ Òkédìjí
Subtitle
Oladejo Okediji's use of Language in his novels
Course
B. A YORÙBÁ
Grade
83.2%
Author
Year
2017
Pages
82
Catalog Number
V434477
ISBN (eBook)
9783668758971
File size
894 KB
Language
English
Notes
This work written in Contemporary Yoruba language focuses on the famous Oladejo Okediji detective novels and the use of language therein. Idioms and proverbs are the major areas of concentration and thus work is a relevant contribution to Yoruba studies.
Keywords
Àkànlò èdè, Use of Language, Okediji, Agbalagba Akan, Atoto Arere, Aja lo leru
Quote paper
Jacob Gbenga (Author), 2017, Ìlò Àkànlò èdè nínú Àwọn Ìwé Ìtàn Àròsọ Ọladẹ̀jọ Òkédìjí, Munich, GRIN Verlag, https://www.grin.com/document/434477

Comments

  • No comments yet.
Look inside the ebook
Title: Ìlò Àkànlò èdè nínú Àwọn Ìwé Ìtàn Àròsọ Ọladẹ̀jọ Òkédìjí



Upload papers

Your term paper / thesis:

- Publication as eBook and book
- High royalties for the sales
- Completely free - with ISBN
- It only takes five minutes
- Every paper finds readers

Publish now - it's free